Ni ọsẹ kẹjọ, iwọn ida marundinlọgọrin ninu
ọgọrun ọmọ inu oyun ni maa lo ọwọ ọtun.
Awọn yoku ni a le pin si
awọn ti yio lo ọwọ osi, ati awọn ti yio lo mejeeji.
Eyi ni o kọkọ fi
iwa lilo ọwọ ọtun tabi ọwọ osi han.
Iwe ẹkọ nipa ilera awọn ọmọde
se apejuwe “yiyirapada ọmọde”
gẹgẹbi iS̩ẹlẹ tii maa waye
laarin ọsẹ kẹwa si ogun ọsẹ lẹhin ibimọ.
sugbọn iru iwa ti o yanilẹnu yi
ma nsaba waye nibiti
agbara ti nfa ohun gbogbo walẹ ko ti pọ,
ninu apo ile-ọmọ,
eyiti omi kun inu rẹ.
Aini agbara ti o pọ to
lati bori agbara ti nfa ohun gbogbo walẹ yi
ni ayika ti o yatọ si ti ile-ọmọ, ni ko le
jẹki ọmọ ti a sẹsẹ bi le yi ara rẹ pada.
Ni asiko yi,ọmọ inu oyun naa
ti dagbasoke lati ẹyin kekere kanS̩oS̩o
si ọkẹ aimọye ẹyin keekeke,
eyiti yio di awọn orisirisi ẹya ara
miran ti o le ni ẹgbẹrun mẹrin.
Ọmọ inu oyun naa ni
ida aadọrun ninu ọgọrun
ẹya ara agbalagba enia.