Skip Navigation
The Endowment for Human Development
The Endowment for Human Development
Improving lifelong health one pregnancy at a time.
Donate Now Get Free Videos

Multilingual Illustrated DVD [Tutorial]

The Biology of Prenatal Development




ẸKỌ NIPA IDAGBASOKE ỌMỌ NINU OYUN KI A TO BI I S’AYE

.Yoruba


National Geographic Society This program is distributed in the U.S. and Canada by National Geographic and EHD. [learn more]

Choose Language:
Download English PDF  Download Spanish PDF  Download French PDF  What is PDF?
 

Chapter 1   Introduction

Ọna ti oyun inu ọmọ enia ti o ni ẹyin kekere kanlolo ngba ti agbalagba enia ti o ni ẹgbẹrun lọna aadọjọ ẹyin keekeke jẹ ifarahan ti o yanilẹnu julọ ninu ohun gbogbo ti o wa laye.

Awon oluwadi ti mọ bayi wipe, pupọ ninu awæn isẹ ojoojumọ ti ara agbalagba enia nse ni a ti filelẹ lati inu oyun wa – nigba pupọ, ki a to bi ni s’aye.

Akoko idagbasoke ki ọmọ to o w’aye ni o tubọ nye ni sii gẹgẹbi akoko ipalẹmọ, ninu eyiti ọmọ enia ti o sẹsẹ ndagbasoke njẹ ere orisirisi awọn ẹya-ara, ti o si nfi orisirisi ọgbọn han, eyiti yio lo fun wiwa laaye lẹhin ti a ba bii tan.

Chapter 2   Terminology

Oyun lara ọmọ enia ma ngba to ọsẹ mejidinlogoji ti a ba kaa lati igbati idapọ ba ti w’aye laarin ẹyin ọkunrin ati obirin, tabi lati igbati enia loyun, titi di asiko ibimọ.

Ni ọsẹ mẹjọ ekini lẹhin idapọ ẹyin ọkunrin ati obirin, ọmọ enia ti i ndagbasoke ninu ni a npe ni ẹmubirayoo, eyiti o tumọ si “idagbasoke ninu." Akoko yi, ti a npe ni akoko ẹmubirayoo, ma nfarahan nipa fifi awọn orisirisi ẹya-ara le lẹ.

Lati igbati ọsẹ mẹjọ ba kọja, titi di opin iloyun, "ọmọ enia ti ndagbasoke ninu yi ni a npe ni fitọọsi,” itumọ eyiti nse "ọmọ ti a ko i tii bi." Ni akoko yi, eyiti a npe ni akoko fitọọsi, gbogbo ẹya-ara ọmọ naa yio dagbasoke sii, wọn yio si maa sisẹ.

Gbogbo awọn akoko iloyun ti o wa ninu eto yi ntọka si akoko ti o bẹrẹ lati igbati idapọ ẹyin ọkọ ati aya ti w’aye.

The Embryonic Period (The First 8 Weeks)

Embryonic Development: The First 4 Weeks

Chapter 3   Fertilization

Bi a ba nsọrọ nipa awọn ohun alaaye, "idagbasoke enia bẹrẹ lati igbati idapọ ba w’aye laarin ẹyin ọkunrin ati obirin," nigbati ọkunrin ati obirin ba da mẹtaleloogun ninu awọn eroja ti o wa ninu ẹya-ara wọn pọ, nipasẹ idapọ ẹya-ara ti o wa fun ọmọ bibi.

Ẹya-ara ti o wa fun ọmọ bibi ninu ara obirin ni a npe ni "ẹyin" Sugbọn ohun ti o yẹ ki a pee ni oosaiti.

Bakanna, ẹya-ara ti o wa fun ọmọ bibi lara ọkunrin ni a npe ni "sipaamu," Sugbọn ọrọ ti o dara julọ fun eyi ni sipamatosoonu.

Lẹhin ti ẹyin ba ti jade tan kuro ninu apo ẹyin obirin nipasẹ ọna ti a npe ni ofulesan, ẹyin naa ati sipamatosoonu yio dapọ ninu ọkan lara okun ile ọmọ, eyiti a npe ni okun Falopiani.

Awọn okun ile ọmọ yi ni o so ile ẹyin obirin pọ mọ ile ọmọ tabi wohunbu.

Abajade idapọ yi ni nfa oyun, eyiti a npe ni saigọọti, itumọ eyiti nS̩e "isopọ tabi idapọ sọkan."

Chapter 4   DNA, Cell Division, and Early Pregnancy Factor (EPF)

Awọn eroja mẹrindinlaadọta ti o wa ninu saigọọti duro fun ekini ninu awọn alailẹgbẹ eto igbesi aye ọmọ enia titun. Eto pataki yi wa ninu awọn ohun kan ninu agọ ara ti a npe ni DNA. Ninu wọn ni asẹ fun idagbasoke gbogbo ara enia wa.

Awọn ohun ti a npe ni DNA yi farajọ akaba ti o lọ pọ, ti a npe ni dọbulu hẹlikisi. Lara akasọ ara akaba naa ni awọn ohun kan, ti a npe ni guanini, sitosini, adinini, ati taamini wa.

Guanini yi le darapọ mọ sitosini nikan, adinini si le darapọ mọ taamini. Ọkọọkan ninu awọn ẹyin keekeke ti a fi da enia ni o ni ọkẹ aimoye awọn ohun ti a darukọ loke wọnyi ninu.

DNA inu ọkan ninu awọn ẹyin keekeke ti a fi da enia yi ni oriS̩iriS̩i alaye ninu, ti o jẹ wipe, bi a ba fẹ kọ wọn silẹ ni ọrọ, lẹta ekini ninu ọkọọkan awọn ohun ti a darukọ wọnyi yio gba oju ewe iwe ti o to miliọnu kan ati aabọ!

Bi a ba gbe wọn si ẹgbẹ ara wọn, DNA inu okansoso ninu awọn ẹyin keekeke wọnyi yio gun to iwọn ẹsẹ mẹta ati diẹ tabi mita kan.

Bi a ba le tu gbogbo DNA yi palẹ ninu ọkẹ aimọye ẹyin keekeke ti o wa ni ara agbalagba enia, yio gun to iwọn mẹtalelọgọta biliọnu maili. Gigun rẹ yi to ki a rin irin ajo lati aye lọ si ibiti oorun wa, ati ki a pada ni ọọdun igba, o le ni ogoji.

O fẹrẹ to wakati mẹrinleloogun si ọgbọn wakati lẹhin idapọ ẹyin ọkunrin ati obirin, ki saigọọti to pari pinpin si meji rẹ akọkọ. Nipasẹ ọna ti a npe ni maitosisi, ẹyin kan yio pin si meji,meji yio pin si mẹrin, ati bẹẹbẹẹ lọ.

Laarin wakati mẹrinleloogun si wakati mejidinlaadọta lẹhin ti idapọ ti waye, a le sọ daju pe oyun ti wa nipo, nipasẹ ọkan ninu awọn ohun kan ti a npe ni homonu, eyiti orukọ rẹ njẹ "olufihan oyun inu titun”, ti o wa ninu ẹjẹ iya ọmọ.

Chapter 5   Early Stages (Morula and Blastocyst) and Stem Cells

Laarin ọjọ mẹta si mẹrin lẹhin idapọ ẹyin ọkunrin ati obirin, ẹyin naa yio maa pin si ọna pupọ, wọn a ri rogodo, a si npe oyun inu naa nisisiyi ni morula.

Laarin ọjọ mẹrin si marun, iho kan yio waye laarin awọn ẹyin rogodo wọnyi, a si npe oyun inu naa nisisiyi ni bilasitosisiti.

Awọn ẹyin keekeke ti o wa ninu bilasitosisiti yi ni a npe ni akojọpọ ẹyin ti inu, eyiti yio ko ara wọn jọ pọ lati di ori, ara, ati awọn ẹya ara miran ti o S̩e pataki fun idagbasoke ọmọ enia.

Awọn ẹyin ti a fi ns’ẹda enia, eyiti o wa ninu akojọpọ ẹyin ti inu yi ni a npe ni ẹyin oyun ti o l’ẹka, nitori wipe wọn lagbara lati di ọkan ninu iru awọn orisirisi ẹyin keekeke ti o le ni igba, eyiti o wa ni ara ọmọ enia.

Chapter 6   1 to 1½ Weeks: Implantation and Human Chorionic Gonadotropin (hCG)

Nigbati o ba kuro ninu okun ile ọmọ, oyun inu titun yi yio gbin ara rẹ sinu ẹran ara ti o wa ni ayika ile ọmọ iya rẹ. Ilana yi, ti a npe ni gbigbin nkan, ma nbẹrẹ ni ọjọ kẹfa, yio si pari ni ọjọ kẹwa si ekejila lẹhin idapọ ẹyin ọkunrin ati obirin.

Ẹyin keekeke ara oyun inu ti ndagba yi a bẹrẹ sii mu orisi homonu kan jade, eyiti a npe ni hCG, eyiti o si ma nfarahan nigbati a ba S̩e ayewo lati mọ boya oyun ti duro.

HCG ma ntọ homonu ara iya lati da nkan osu duro, ki oyun baa le dagbasoke siwaju sii.

Chapter 7   The Placenta and Umbilical Cord

Lẹhin ti oyun ba ti gbin ara rẹ si ile ọmọ iya rẹ tan, awọn ẹyin keekeke ti o wa l’ẹba bilasitosisiti yi yio di lara ẹya ohun ti a npe ni ibi-ọmọ, eyiti o so ẹya ara ti ngbe ẹjẹ yika ara iya pọ mọ ti ọmọ inu oyun.

Ibi-ọmọ yi a ma gbe atẹgun, ounjẹ, homonu ati oogun lati ara iya lọ si ara ọmọ inu oyun ti ndagba naa; o si tun ma nmu idọti ara kuro; kii si jẹki ẹjẹ ara iya dapọ mọ ẹjẹ ara ọmọ inu oyun.

Ibi-ọmọ ma nmu awọn homonu jade, o si ma nmu ki iwọn otutu tabi ooru ara ọmọ inu oyun o pọ diẹ ju ti ara iya rẹ lọ.

Ohun ti a fi so ibi-ọmọ pọ mọ oyun inu ni okun ibi-ọmọ.

A le fi ọna ti ibi-ọmọ ngba se atilẹhin fun ẹmi ọmọ inu oyun we iyara ti a ti nse itọju awọn enia ti o wa labẹ ewu, ni ile iwosan igbalode.

Chapter 8   Nutrition and Protection

Lẹhin ọsẹ kan, ẹyin keekeke ti o wa lara akojọpọ ẹyin inu yio di awọ fẹlẹfẹlẹ meji ti a npe ni aipobilasiti ati ẹpibilasiti.

Aipobilasiti yi ni yio di ohun ti a npe ni apo ẹyin, eyiti o jẹ ọkan lara awọn ẹya ara, nipasẹ eyiti iya yio maa gba fun oyun inu rẹ l’ounjẹ.

Ẹyin keekeke lati ara ẹpibilasiti yio di awọ fẹlẹfẹlẹ kan ti a npe ni aminiọnu, ninu eyiti ọmọ inu oyun ti a S̩ẹS̩ẹ ni, ati ọmọ inu oyun ti o ti le ni ọsẹ mẹjọ yio ti maa dagbasoke titi di akoko ibimọ.

Chapter 9   2 to 4 Weeks: Germ Layers and Organ Formation

Lẹhin ọsẹ meji ati aabọ, ẹpibilasiti yio ti di oriS̩i ẹya ara mẹta, tabi awọ fẹlẹfẹlẹ, ti a npe ni ẹkitodaamu, ẹndodaamu, ati mẹsodaamu.

Ekitodaamu yio di awọn oriS̩iriS̩i ẹya ara bii ọpọlọ, ọpa-ẹhin, iS̩an-ara, awọ-ara, eekanna, ati irun.

Ẹndodaamu yio di awọ ti a fi tẹ inu ẹya ara ti atẹgun ngba lara enia ati ti inu ẹya ara ti ounjẹ ngba, yio si tun di lara oriS̩iriS̩i awọn ẹya ara miran bii ẹdọ ati ẹya ara ti oronro ngbe inu rẹ.

Mẹsodaamu yio di ọkan, kidinrin, egungun, kerekere, iS̩an, ẹjẹ, ati awọn ẹya miran.

Lẹhin ọsẹ mẹta ọpọlọ yio pin si ọna mẹta ọtọọtọ ti a npe ni ọpọlọ iwaju, ọpọlọ aarin, ati ọpọlọ ẹhin.

Idagbasoke awọn ẹya ara ti ngbe ẹjẹ ati ounjẹ kaakiri ara ti bẹrẹ pẹlu.

Bi ẹjẹ akọkọ ba ti de inu apo ẹyin, iho ara ti ẹjẹ ngba yio farahan kaakiri lara ọmọ inu oyun naa, bẹẹ si ni ọkan, eyiti o ri rogodo, yio farahan bakanna.

O fẹrẹ jẹ lẹsẹkanna ni ọkan ti ndagbasoke ni kiakia yi yio sẹpo sori ara rẹ, bẹẹ si ni apo ọtọọtọ yio maa waye laarin ọkan naa.

Ọkan naa yio bẹrẹ sii mi lati ọsẹ kẹta ati ọjọ kan lẹhin idapọ ẹyin ọkọ ati aya.

Ẹya ara ti ngbe ẹjẹ kiri gbogbo ara jẹ ẹya ara akọkọ, tabi akojọpọ awọn ẹya ara ti o jọ ara wọn lati bẹrẹ sii S̩iS̩ẹ.

Chapter 10   3 to 4 Weeks: The Folding of the Embryo

Larin ọsẹ mẹta si mẹrin, awọn eto ẹya ara yio yanju, gẹgẹbi ọpọlọ, ọpa-ẹhin, ati ọkan ọmọ inu oyun naa, eyiti a le fi irọrun damọ lati ẹgbẹ apo ẹyin.

Idagbasoke yi ma nmu ki oyun inu ti o ti S̩e pẹrẹsẹ tẹlẹ ri ki o sẹpo. Ilana yi a maa so lara apo ẹyin pọ mọ awọ ti a fi tẹ inu ẹya ara ti ngbe ounjẹ kaakiri ara enia, wọn yio si di aya ati inu ikun ọmọ inu oyun ti ndagba naa.

Embryonic Development: 4 to 6 Weeks

Chapter 11   4 Weeks: Amniotic Fluid

Ni ọsẹ kẹrin, omi-ara ti o mọ tonitoni yi yio san yika ọmọ inu oyun ninu apo ile ọmọ. Omi ti ko ni abawọn yi, ti a npe ni omira, ma ndaabobo oyun inu lọwọ ipalara.

Chapter 12   The Heart in Action

Ọkan enia ma nmi niwọn igba mẹtalelaadọfa laarin isẹju kan.

Sakiyesi bi awọ ara ọkan naa ti nyipada bi ẹjẹ ti nwọ inu awọn iho rẹ, ti o si njade.

Ọkan enia maa nmi niwọn igba mẹrinlelaadọta miliọnu ki a to bi ni, ati niwọn igba miliọnu mẹta, o le diẹ ni igbesi aye enia ti o pe ọmọ ọgọrin ọdun.

Chapter 13   Brain Growth

Idagbasoke ọpọlọ ma nfi ara han nipa bi iyatọ se nwa ninu irisi ọpọlọ iwaju, ọpọlọ aarin, ati ọpọlọ ẹhin.

Chapter 14   Limb Buds

Ọwọ ati ẹsẹ yio bẹrẹ sii yọ jade nigbati idi wọn ba farahan ni ọsẹ kẹrin.

Awọ ara ọmọ inu oyun naa ni asiko yi yio mọ gaara nitori pe ko nipọn pupọ.

Bi awọ ara naa se nnipọn sii, ni mimọ ti o mọ yio maa dinku, eyiti o tumọ si wipe a le maa wo bi awọn ẹya inu ara ti ndagba, fun osu kan sii.