Ni ọsẹ kẹrindinloogun,
ọna kan ti a ngba ki
abẹrẹ sinu ikun ọmọ inu oyun
ma nmu
ifesi kan waye,
eyiti nfa ohun kan
ti a npe ni noradirẹnalini,
tabi norẹpinẹpirini wọ inu ẹjẹ.
Ọmọ ti a S̩ẹS̩ẹ bi
ati agbalagba paapa ma nse bayi
nigbati ohun ajeji kan
ba fẹ wọnu ara wọn.
Ohun kan funfun,
ti o wa fun aabo,
eyiti a npe ni famisi kasehosa,
yio bo gbogbo ara ọmọ inu oyun naa.
Famisi yi ma ndaabobo awọ-ara
kuro lọwọ awọn ohun ti npanilara,
eyiti o wa ninu omira
ti o wa ni apo ile-ọmọ.
Ni ogun ọsẹ, apa kan ninu iho eti,
eyiti o jẹ ẹya ara ti igbọran,
yio ti tobi to ti agbalagba
ninu
iho eti ti o ti dagbasoke tan naa.
Lati igba yi lọ,
ọmọ inu oyun yio maa fesi
si oriS̩iriS̩i ariwo.
Ni ọsẹ kọkanleloogun
si ikejileloogun lẹhin idapọ,
ẹdọforo yio lagbara
lati maa mi atẹgun sinu.
Ọmọ inu oyun le gbe ile-aye nisinsinyi,
nitori pe wiwa laaye
ni ode apo ile-ọmọ
yio S̩ee S̩e fun
awọn ọmọ inu oyun kan.
OriS̩iriS̩i awọn aseyọri
ninu ẹkọ ilera
njẹki o S̩ee S̩e lati mu ẹmi
awọn ọmọ ti osu wọn ko pe duro.