Laarin ọsẹ kẹrin si ikarun,
ọpọlọ yio maa dagbasoke ni kiakia sii,
yio si pin si ọna marun ọtọọtọ.
Ori jẹ iwọn kan ninu idamẹta
gbogbo ara ọmọ inu oyun naa.
Ọpọlọ iwaju
yio gba aaye ti o pọ fun ara rẹ,
yio si di ẹya ti o tobi ju ninu ọpọlọ.
Awọn iS̩ẹ ti ọpọlọ iwaju yi wa fun
ni ironu, ẹkọ kikọ,
iranti nkan, ọrọ sisọ, iriran,
igbọran, gbigbe ọwọ tabi ẹsẹ,
ati yiyanju ọran ti o S̩oro.